Skip to main content

IROYIN TO N KAN!!!! IROYIN TO N KAN!!!!!

By Kemi Trump Flash

E karo o, e ku ojo meta lati odo Oludari we iroyin, Iroyin to n kan. Se ode dun, se a ri je . Se atije wa ko da bi ti awon omo Eli ti n fi igboju je ohunje ti ko to si won?.

Akori iwe iroyin wa toni ni.....
ODUN MEJI LEYIN IFIBO SOFO!!!

Osu karun odun yi lo pe odun meji gbako ti awon alakoba bi milioni marundinlogun fi ibo abenilori gbe arugbo ojo kan lati Oke Oya wole lati je olori orile ede yi.

Yiyan re ninu egbe Oselu kan to je iparapo awon madaru oke ohun ati awon afoworoye ile Yoruba da bi igba ti ogun aye parapo mo ogun orun lati fi iya je nijiria ni.

Gbogbo ariwo ati alaye ti awon egbe alatako igba yen se pelu akosile ati irannileti ohun ateyinwa si ibi ti oludije na se seyin ni a gbo. Gbogbo iwa jegudujera awon alatileyin re gbogbo ni a gbo, sugbon Yoruba so wipe aja ti yio sonu ko ni gbo fere olode.

Gbogbo atako igba na lo da lori pe...
1. Oludije yi ti dagba ju ni ojo ori. Ise olori ko easiiiiiii
?. Okunrin Daura yi ko ni aseyori kankan ninu ise adani tire
3. Lati igba to ti fori oye sile bi ogbon odun seyin, ko ko iwe, ko lo si idanlleko kankan, a ko fi oruko re pe ohun meremere kankan ni orile ede yi.
4. O ko lati lo si ipade awon Olori ana gbogbo ni ibi ti o ye fun lati mo nipa oselu ati iselu akoko ti a wa yi.
5.A si sakiyesi nijiria si pe okunrin yi ko gbadun, pe ailera to ni se pelu agba dida yi o ma da lamu.

Kete ti alagba yi wole ni wahala bere bi obinri ti ojo atibimo de si lojiji. Ni ata ko to mo,ti iyo wa ko dun obe, larelu ati ajalu nipa oro aje bere, ni awon osise bere si padanu ise won lotun losi , ni awon ile ise bere si ko igba wole, airi owo osu awon osisesan wa di aso egbejoda ni gbogbo Ipinle, ni ailarojinle bere si mu awon eniyan ro aropin pe iku lo ku.

Bi aisan se tile tun wa ko lu Baba ohun. Ni baba wa n fi oni ku fola dide. Bi mo se n ko iroyin yi , Orile ede yi ko le so pato Ilu ti Are ti n gba itoju, be ni a ko tile mo iru arun ti n pa baba looooo, be egbe gberun milionu owo oke okun ni ilu ti nan ti ara baba koo bi eni laaan kogbogun.

Se awon minisita ti won ko nise se gbogbo ni ka so ni, tabi awon oludamoran ti n fi owo ilu ge koriko aramanda. Awon amugbalegbe re gbogbo ti so ara won di kan ti awon oloyinbo n pe ni Kabali, ti won n selu fun baba nigba ti aisan ko fun laye lati se.

Leyin odun meji yiiii, ibo la de duro gan

1. Ni akoko, ko si olori ti a dibo yan nile bayi. Igba keji re Omowe Oshin lo n se ijoba sekele ti awon Kabali ba faye gba. Lati bi Osu meji ti Baba Afarunjoye ti lo, ose to koja ni aye sese de lati ori akete aisan pe ki Oshin bu owo lu eto isuna odun yi ninu osu kefa!!!.

2. Milionu bi mefa osise lo ti padanu ona atije won ninu odun meji yi . Opolopo idile lo ti fara ko wahala ati idamu. Be akosile ati ileri ijoba yi ni lati pese ise milionu meta lodun.

3. Okunkun su bo ilu oooooo, ko sina, ko somi,ko sona, ko soja, ko salafia .

4. Iroyin fi ye wa pe ninu odun meji yi, gbese orile ede yi ti di gobohi, trilionu bi mewa ti gun. Kaiiiii! Ki ni won nan si!!!!?????????

5. Ogun Boko Haramu ti Baba ni ohun yi o parun ni osu kan ti ohun ba gori oye ko ma dekun,awon eni ibi wonyi mura si bi igba ti won gbominira niii.

6. Ai ni ife ti wa fi idi mule larin gbogbo awon eya ni orile ede yi. Awon hausa n binu, awon Igbo fe lo labe Biafa, awon ti eti osa ko simi, yoruba n pete adani Oduduwa, o ma se ooo, Olori apini niya la ni yi!!!!

7. Oro igbogun ti ibaje ati iwa jegudujera ti di oro yeye. Awon to yi Aare ka gan je idile Anini. Awon ile ise ton koju oro ibaje bi efcc ni olori ti ko lopolo, ojojumo lo n ri owo ninu salanga, ipo oku ati ile adani. Gbogbo owo na ni ko ni oruko awon to ji. Agaga ti enikeni ba soro odi si ijoba, owo yi o farahan nile re

8.Ni afikun, atuto ati atuse oro aje wa to ti daru ko ye minisita ti a fi sibe. Ko ni oye to, ko ni imo to, ko mo eniyan to, ko jade to. Gbogbo ofin ati agbekale re ko mu atuse wa,o n baje si ni . Ko ri ona abayo.

9. Aibikita fun ofin ti gbinle. Gbogbo awon ti ijoba fi esun kan ti won ti mole, ti ile ejo ni kan da won sile lati ma tile wa si kootu ni ijoba ko jale lati fi sile.

10. Airi owo osu awon osise san ni opolopo Ipinle n fa ebi ati aifokanbale ni orile ede yi. Awon Ipinle bi Kogi ati Osun je owo ju odun kan lo.

Leyin odun meji , o ti re wa, o ti sun wa, ireti iserere ijoba yi ti pin. Ko si olori nile, awon omo eyin ko suwon. Nijiria ti gbe omi wo a ti gbe iyo wo a ti mo eyi ti o wuwo.

Adura wa ni pe ki Olorun gbo adura wa lori Orile Ede yi. Eni to ba ye ko kuro, ko kuro, eni to ba ye ko wa, ko wa, eni to ba ye ko ku, ko ku, ijoba to ba ye ko faya, ko faya.Ipinya awon eya to ba ye ko sele, ko sele.

Mo gbadura ki odun meji to ku ma gbemi wa.

E karo, ojumo ire.
Kemi Trump Flash, 2017

Comments

Popular posts from this blog

APC Governorship Aspirant, Atinuke Omolayo, Participates in Delegate Congress in Emure

October 25, 2025 A former governorship aspirant of the All Progressives Congress (APC) in Ekiti State, Mrs. Atinuke Oluremi Omolayo (née Okeya), who was duly screened and cleared by the party’s National Screening Committee, has demonstrated uncommon party loyalty by stepping down for Governor Biodun Abayomi Oyebanji and actively participating in the delegate congress held today in her Eporo Ward, Emure Local Government Area. Mrs. Omolayo, who was warmly received with an Ọ̀wọ̀ song by jubilant party members, expressed appreciation to her ward for the support they gave her when she initially declared her intention to contest for governor. She explained that her decision to step down for Governor Oyebanji was informed by his wide acceptability across the state, sterling performances in office, and commitment to Ekiti’s growth and development, which she described as derivatives of continuity. While addressing the crowd, Mrs. Omolayo urged party members in Eporo Ward...

Ignore Rumours: APC Confirms Governor Oyebanji’s Name to Be Submitted to INEC on January 16, 2026

…As APC Spokesperson Reiterates Official Candidate List Ahead of Publication The APC Integrity Caucus has moved to dismiss what it describes as a reckless and senseless rumour being circulated by a few individuals posing as party members. The gossip, they said, claims that the party “does not intend to submit” the name of Governor Biodun Abayomi Oyebanji to the Independent National Electoral Commission (INEC). In a statement released on Thursday, November 14, 2025, the caucus said such claims are baseless and should be ignored by every well-meaning member of the public. “Since the successful conduct of our governorship primary on October 27 and the ratification by authorised delegates on October 29, some mischief makers have been whispering that the party will not submit Governor Oyebanji’s name to INEC. This is completely false,” the statement read. The caucus emphasized that the APC operates according to a clearly defined timetable, which specifies the dates for submissio...

Tinubu’s Son-in-Law, Oyetunji Ojo, Declares President’s Full Support for Oyebanji’s Second Term

…Promises to Lead Campaign Across 16 LGAs of Ekiti State   September 26, 2025  The cordial relationship between President Bola Ahmed Tinubu and Governor Biodun Abayomi Oyebanji (BAO) was brought into focus on Friday when Honourable Oyetunji Ojo, Chairman of the Federal Housing Authority and son-in-law to President Tinubu, visited the Ekiti State Secretariat of the All Progressives Congress (APC). Ojo told the State Executive Council that President Tinubu was firmly backing Governor Oyebanji’s re-election, describing the bond between the two leaders as “smooth, cordial and unwavering.” He stressed that the relationship between the Presidency and the Government of Ekiti State would only grow stronger in the years ahead. The FHA Chairman hailed Oyebanji as a “tested, trusted, and people-focused leader” who has delivered on his promises through achievements in infrastructure, human capital development and inclusive governance.  He pledged t...